Luke 9:1-2

Jesu rán ọmọ-ẹ̀yìn méjìlá lọ wàásù

1 aÓ sì pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá jọ, ó sì fún wọn ní agbára àti àṣẹ lórí àwọn ẹ̀mí èṣù gbogbo, àti láti wo ààrùn sàn. 2Ó sì rán wọn lọ wàásù ìjọba Ọlọ́run, àti láti mú àwọn ọlọkùnrùn láradá.
Copyright information for YorBMYO